Jobu 6

Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ, nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé.

Job 6:3 (UKJV) For now it would be heavier than the sand of the sea: therefore my words are swallowed up.

1Jobu sì dáhùn ó si wí pé,

2“Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òsùwọ̀n, kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òsùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!

3Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ, nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé.

4Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú, oró èyí tí ọkàn mi mú; ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.

5Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko, tàbí ọ̀dá màlúù a máa dún lórí ìjẹ rẹ̀?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.