3Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí? Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre?
4Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i, ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn.
5Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò, tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè.
6Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin: ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ, òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.
7Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í, bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.