2“Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó? Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá?
3Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí? Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre?
4Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i, ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn.
5Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò, tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè.
6Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin: ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ, òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.