24Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.
25Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a.
26Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà Olúwa.
27Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.
28Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí Olúwa ti fi fún un.