21Àwọn ọmọ Peresi: ti Hesroni, ìdílé Hesroni; ti Hamulu, ìdílé Hamulu.
22Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógójì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (76,500).
23Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Tola, ìdílé Tola; ti Pufa, ìdílé Pufa;
24ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu; ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni.
25Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (64,300).