11A ó pa ilé ènìyàn búburú run, ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i.
12Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú.
13Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora; ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́.
14A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀, ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.
15Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.