18Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà; àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀.
19Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀; bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.
20Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́, ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.
21Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn, ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.
22Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.