37Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà tí yóò máa so èso tí ó dára;
38Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù.
39Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú, ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù,
40ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí.
41Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran.