35O sọ aginjù di adágún omi àti ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi,
36níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà, wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé.
37Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà tí yóò máa so èso tí ó dára;
38Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù.
39Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú, ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù,