1Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
2Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin, ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
3Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ; kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
4Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀; wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.