Saamu 44

ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa, ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.

Psalm 44:7 (UKJV) But you have saved us from our enemies, and have put them to shame that hated us.

5Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú; nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀,

6èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi, idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,

7ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa, ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.

8Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́, àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. Sela.

9Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá, Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.