1Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn! Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
2Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
3Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
4èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe, èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.
5Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé? Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,