Saamu 68

Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè, tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.

Psalm 68:33 (UKJV) To him that rides upon the heavens of heavens, which were of old; lo, he does send out his voice, and that a mighty voice.

31Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti; Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.

32Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé, kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela.

33Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè, tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.

34Kéde agbára Ọlọ́run, ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli, tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.

35Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ; Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ. Olùbùkún ní Ọlọ́run!

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.