Saamu 71

Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́.

Psalm 71:9 (UKJV) Cast me not off in the time of old age; forsake me not when my strength fails.

7Mo di àmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

8Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi, ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.

9Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́.

10Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi, àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.

11Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu, nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.