1Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli, fún àwọn ọlọ́kàn funfun.
2Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán; ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
3Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.
4Wọn kò ṣe wàhálà; ara wọn mókun wọn sì lágbára.
5Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn; a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.