3Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.
4Wọn kò ṣe wàhálà; ara wọn mókun wọn sì lágbára.
5Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn; a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
6Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn; ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.
7Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá; ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n.