Saamu 78

ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.

Psalm 78:3 (UKJV) Which we have heard and known, and our fathers have told us.

1Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi; tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

2Èmi ó la ẹnu mi ní òwe, èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;

3ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.

4Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀.

5Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli, èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.