34Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.
35Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra; èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.
36Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé, àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.
37A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá, àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run.” Sela.
38Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra; ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró rẹ.