10Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí? Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?
11Olúwa mọ èrò inú ènìyàn; ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.
12Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ìwọ bá wí, Olúwa, ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ,
13Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi, títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.
14Nítorí Olúwa kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.