Saamu 94

Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi, títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.

Psalm 94:13 (UKJV) That you may give him rest from the days of adversity, until the pit be dug for the wicked.

11Olúwa mọ èrò inú ènìyàn; ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.

12Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ìwọ bá wí, Olúwa, ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ,

13Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi, títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.

14Nítorí Olúwa kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.

15Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo, àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀lé e lẹ́yìn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.