7Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì, àwọn tí ń fi ère gbéraga, ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!
8Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn inú àwọn ilé Juda sì dùn, nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa.
9Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.
10Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́ ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn.