Orin Solomoni 8

Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́ èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi, ìwọ ìbá kọ́ mi. Èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòórùn dídùn fún ọ mu, àti oje èso pomegiranate mi.

Song of Solomon 8:2 (UKJV) I would lead you, and bring you into my mother's house, who would instruct me: I would cause you to drink of spiced wine of the juice of my pomegranate.

1Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi si mi, èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà! Èmi ìbá rí ọ ní òde, èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu, wọn kì bá fi mí ṣe ẹlẹ́yà.

2Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́ èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi, ìwọ ìbá kọ́ mi. Èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòórùn dídùn fún ọ mu, àti oje èso pomegiranate mi.

3Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbà mí mọ́ra.

4Ọmọbìnrin Jerusalẹmu, èmi pè yín ní ìjà. Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè. Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.