1 Kronika 7

Àwọn ọmọ Beriah: Heberi àti Malkieli, tí ó jẹ́ baba Barsafiti.

1 Chronicles 7:31 (UKJV) And the sons of Beriah; Heber, and Malchiel, who is the father of Birzavith.

29Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Manase ni Beti-Ṣeani, Taanaki, Megido àti Dori lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.

30Àwọn ọmọ Aṣeri: Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn sì jẹ́ Sera.

31Àwọn ọmọ Beriah: Heberi àti Malkieli, tí ó jẹ́ baba Barsafiti.

32Heberi jẹ́ baba Jafileti, Ṣomeri àti Hotami àti ti arábìnrin wọn Ṣua.

33Àwọn ọmọ Jafileti: Pasaki, Bimhali àti Asifati. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jafileti.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.