Amosi 5

Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀.

Amos 5:7 (UKJV) All of you who turn judgment to wormwood, and leave off righteousness in the earth,

5ẹ má ṣe wá Beteli, ẹ má ṣe lọ sí Gilgali, ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Beerṣeba. Nítorí dájúdájú a ó kó Gilgali ní ìgbèkùn, A ó sì sọ Beteli di asán.”

6Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè, kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfu a sì jó o run Beteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á.

7Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀.

8Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀ tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀ ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀ tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀ Olúwa ni orúkọ rẹ̀,

9Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.