Amosi 9

Bí wọ́n tilẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní iwájú àwọn ọ̀tá wọn láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà kí ó ṣá wọn pa. “Èmi yóò sì tẹ ojú mi mọ́ wọn fún ìbí, kì í sì í ṣe fún rere.”

Amos 9:4 (UKJV) And though they go into captivity before their enemies, thence will I command the sword, and it shall slay them: and I will set mine eyes upon them for evil, and not for good.

2Bí wọ́n tilẹ̀ wa ilẹ̀ lọ sí ipò òkú, láti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ gun òkè ọ̀run lọ, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀kalẹ̀.

3Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Karmeli, èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìsàlẹ̀ Òkun, láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán.

4Bí wọ́n tilẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní iwájú àwọn ọ̀tá wọn láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà kí ó ṣá wọn pa. “Èmi yóò sì tẹ ojú mi mọ́ wọn fún ìbí, kì í sì í ṣe fún rere.”

5Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ilẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ṣọ̀fọ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Naili tiwọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Ejibiti.

6Òun ni ẹni tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé, Ẹni ti ó pe àwọn omi Òkun ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé Olúwa ni orúkọ rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.