Isaiah 25

Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò bọ̀wọ̀ fún ọ; àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóò bu ọlá fún ọ.

Isaiah 25:3 (UKJV) Therefore shall the strong people glorify you, the city of the terrible nations shall fear you.

1Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run mi; èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́ o ti ṣe ohun ńlá, àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.

2Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà, ìlú olódi ti di ààtàn, ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́; a kì yóò tún un kọ́ mọ́.

3Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò bọ̀wọ̀ fún ọ; àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóò bu ọlá fún ọ.

4Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀ ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru. Nítorí pé èémí àwọn ìkà dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri

5àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù. O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì, gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.