2Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà, ìlú olódi ti di ààtàn, ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́; a kì yóò tún un kọ́ mọ́.
3Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò bọ̀wọ̀ fún ọ; àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóò bu ọlá fún ọ.
4Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀ ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru. Nítorí pé èémí àwọn ìkà dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri
5àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù. O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì, gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.
6Ní orí òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ti pèsè àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́ ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì tí ó gbámúṣé.