Isaiah 28

Ègbé ni fún adé ìgbéraga, fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu, àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú àti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀.

Isaiah 28:1 (UKJV) Woe to the crown of pride, to the drunkards of Ephraim, whose glorious beauty is a fading flower, which are on the head of the fat valleys of them that are overcome with wine!

1Ègbé ni fún adé ìgbéraga, fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu, àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú àti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀.

2Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun, gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá, òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.

3Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu, ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.