15Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ? Òun ti bá mi sọ̀rọ̀ àti pé òun tìkára rẹ̀ ló ti ṣe èyí. Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi nítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí.
16Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé; àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú wọn pẹ̀lú. Ìwọ dá ìlera mi padà kí o sì jẹ́ kí n wà láààyè.
17Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni, ní ti pé mo ní ìkorò ńlá. Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́, kúrò nínú ọ̀gbun ìparun; ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.
18Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́, ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ; àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.
19Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí; àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.