19Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli padà wá pápá oko tútù rẹ̀ òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani, a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè Efraimu àti ní Gileadi.
20Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun; àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí.
21“Kọlu ilẹ̀ Merataimu àti àwọn tí ó ń gbé ní Pekodi. Lépa rẹ pa, kí o sì parun pátápátá,” ni Olúwa wí, “Ṣe gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.
22Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá.
23Báwo ni ó ṣe fọ́, tí ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó, lọ́wọ́ òòlù gbogbo ayé! Báwo ní Babeli ti di ahoro ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè.