22Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a; àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́jọ lé e lórí.
23Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun, Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́, yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.
24Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn; ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.
25O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára; idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá. Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀;
26òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀. Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run.