9Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀, nígbà tí ìpọ́njú bá dé sí i?
10Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè? Òun ha lé máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo?
11“Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run: ọ̀nà tí ń bẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pamọ́.
12Kíyèsi i, gbogbo yín ni ó ti rí i; kín ni ìdí ọ̀rọ̀ asán yín?
13“Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmarè.