Jobu 34

Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe, yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀.

Job 34:11 (UKJV) For the work of a man shall he render unto him, and cause every man to find according to his ways.

9Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn, tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’

10“Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi, ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye: Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú, àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé!

11Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe, yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀.

12Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkiwà; bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po.

13Ta ni ó fi ìtọ́jú ayé lé e lọ́wọ́, tàbí ta ni ó fi gbogbo ayé lé e lọ́wọ́?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.