7Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu, tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?
8Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.
9Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn, tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’
10“Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi, ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye: Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú, àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé!
11Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe, yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀.