Jobu 34

Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa; ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa.

Job 34:4 (UKJV) Let us choose to us judgment: let us know among ourselves what is good.

2“Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye.

3Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò.

4Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa; ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa.

5“Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi; Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ.

6Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí, bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.