4Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa; ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa.
5“Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi; Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ.
6Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí, bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’
7Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu, tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?
8Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.