24Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga, ti ènìyàn ni yín nínú orin.
25Olúkúlùkù ènìyàn a máa rí i; ẹni ikú a máa wò ó ní òkèrè.
26Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.
27“Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀, kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀,
28tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lórí ènìyàn.