16Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.
17Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
18Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni: Libni àti Ṣimei.
19Àwọn ìdílé Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.
20Àwọn ìdílé Merari ni: Mahili àti Muṣi. Wọ̀nyí ni ìdílé Lefi gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.