Saamu 69

Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.

Psalm 69:30 (UKJV) I will praise the name of God with a song, and will magnify him with thanksgiving.

28Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè kí á má kà wọ́n pẹ̀lú àwọn olódodo.

29Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí, Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè.

30Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.

31Eléyìí tẹ́ Olúwa lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.

32Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀: ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.