Saamu 83

Bí iná ti í jó igbó, àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,

Psalm 83:14 (UKJV) As the fire burns a wood, and as the flame sets the mountains on fire;

12tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà, bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.

14Bí iná ti í jó igbó, àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,

15bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.

16Fi ìtìjú kún ojú wọn, kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.