Saamu 83

Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ; wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.

Psalm 83:3 (UKJV) They have taken crafty counsel against your people, and consulted against your hidden ones.

1Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́; má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.

2Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ, bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.

3Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ; wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.

4Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè, kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”

5Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan; wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.