16Naomi sì gbé ọmọ náà lé orí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀.
17Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, “A bí ọmọkùnrin kan fún Naomi.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Obedi. Òun sì ni baba Jese tí í ṣe baba Dafidi.
18Èyí ni ìran Peresi: Peresi ni baba Hesroni,
19Hesroni ni baba Ramu, Ramu ni baba Amminadabu
20Amminadabu ni baba Nahiṣoni, Nahiṣoni ni baba Salmoni,