Isaiah 32

Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́, àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.

Isaiah 32:3 (UKJV) And the eyes of them that see shall not be dim, and the ears of them that hear shall hearken.

1Wò ó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodo àwọn olórí yóò máa fi ìdájọ́ ṣe àkóso.

2Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ bí ibi ìṣápamọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì, gẹ́gẹ́ bí odò omi ní ilẹ̀ aṣálẹ̀, àti bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.

3Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́, àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.

4Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè, àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.

5A kò ní pe òmùgọ̀ ní ọlọ́lá mọ́ tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún aláìlóòótọ́ ènìyàn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.