9Bakbukiah àti Unni, àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró sí òdìkejì wọn nínú ìsìn.
10Jeṣua ni baba Joiakimu, Joiakimu ni baba Eliaṣibu, Eliaṣibu ni baba Joiada,
11Joiada ni baba Jonatani, Jonatani sì ni baba Jaddua.
12Ní ìgbé ayé Joiakimu, wọ̀nyí ni àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn àlùfáà: ti ìdílé Seraiah, Meraiah; ti ìdílé Jeremiah, Hananiah;
13ti ìdílé Esra, Meṣullamu; ti ìdílé Amariah, Jehohanani;