54Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi níbikíbi tí èmi ń gbé.
55Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
56nítorí tí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
57Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa: èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
58Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.