56nítorí tí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
57Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa: èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
58Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
59Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
60Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.